Native Bible

Matthew 26:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ àìwúkàrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ Jesu wá pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a pèsè sílẹ̀ láti jẹ àsè ìrékọjá?”

Matthew 26:17 in English

Matthew 26:17 · Berean Standard Bible

On the first day of the Feast of Unleavened Bread,* the disciples came to Jesus and asked, “Where do You want us to prepare for You to eat the Passover?”

Context

15Òun sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jesu lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà. Ó sì gbà á. 16Láti ìgbà náà lọ ni Judasi ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́. 17Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ àìwúkàrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tọ Jesu wá pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a pèsè sílẹ̀ láti jẹ àsè ìrékọjá?” 18Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ wọ ìlú lọ, ẹ̀yin yóò rí ọkùnrin kan, ẹ wí fún un pé, ‘Olùkọ́ wa wí pé, àkókò mi ti dé. Èmi yóò sì jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ.’ ” 19Nítorí náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe gẹ́gẹ́ bí Jesu ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú oúnjẹ àsè ti ìrékọjá níbẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.