Native Bible

Matthew 26:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn aposteli méjìlá ti à ń pè ní Judasi Iskariotu lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.

Matthew 26:14 in English

Matthew 26:14 · Berean Standard Bible

Then one of the Twelve, the one called Judas Iscariot, went to the chief priests

Context

12Nípa dída òróró ìkunra yìí sí mi lára, òun ń ṣe èyí fún ìsìnkú mi ni. 13Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, a ó sì máa ṣe ìrántí rẹ̀ nígbà gbogbo fún ìṣesí rẹ̀ yìí. Níbikíbi tí a bá ti wàásù ìyìnrere yìí ní gbogbo àgbáyé ni a ó ti sọ ìtàn ohun tí obìnrin yìí ṣe.” 14Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn aposteli méjìlá ti à ń pè ní Judasi Iskariotu lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 15Òun sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jesu lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà. Ó sì gbà á. 16Láti ìgbà náà lọ ni Judasi ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.