Matiu 25:35
Matthew 25:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òǹgbẹ gbẹ mí, ẹ̀yin sì fún mi ní omi. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín.
Matthew 25:35 in English
Matthew 25:35 · Berean Standard Bible
For I was hungry and you gave Me something to eat, I was thirsty and you gave Me something to drink, I was a stranger and you took Me in,
Context
33Òun yóò sì fi àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún àti ewúrẹ́ sí ọwọ́ òsì. 34“Nígbà náà ni ọba yóò wí fún àwọn tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún fún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. 35Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òǹgbẹ gbẹ mí, ẹ̀yin sì fún mi ní omi. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín. 36Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi, àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò.’ 37“Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò fèsì pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a sì fún ọ ní oúnjẹ? Tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́ tí a sì fún ọ ní ohun mímu?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.