Native Bible

Matthew 24:44 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wákàtí àìròtẹ́lẹ̀ ni dídé Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́.

Matthew 24:44 in English

Matthew 24:44 · Berean Standard Bible

For this reason, you also must be ready, because the Son of Man will come at an hour you do not expect.

Context

42“Nítorí náà, ẹ múra sílẹ̀, nítorí ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín yóò dé. 43Ṣùgbọ́n, kí ẹ mọ èyí pé, baálé ilé ìbá mọ wákàtí náà tí olè yóò wá, ìbá máa ṣọ́nà, òun kì bá ti jẹ́ kí a já wọ ilé rẹ̀. 44Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ wà ní ìmúrasílẹ̀, nítorí ní wákàtí àìròtẹ́lẹ̀ ni dídé Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́. 45“Ǹjẹ́ olóòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n ọmọ ọ̀dọ̀ wo ni olúwa rẹ̀ lè fi ṣe olùbojútó ilé rẹ̀ láti bọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́? 46Alábùkún fún ni ọmọ ọ̀dọ̀ ti olúwa rẹ̀ dé tí ó sì bá a lórí iṣẹ́ ṣíṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.