Native Bible

Matthew 24:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ‘ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ,’ tí ó bá dúró ní ibi mímọ́ (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á kí ó yé e),

Matthew 24:15 in English

Matthew 24:15 · Berean Standard Bible

So when you see standing in the holy place ‘the abomination of desolation,’* described by the prophet Daniel (let the reader understand),

Context

13ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítì í dópin ni a ó gbàlà. 14A ó sì wàásù ìyìnrere nípa ìjọba náà yìí ní gbogbo ayé ká, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé. 15“Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ‘ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ,’ tí ó bá dúró ní ibi mímọ́ (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á kí ó yé e), 16nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè. 17Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.