Native Bible

Matthew 23:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin gbìyànjú láti farahàn bí ènìyàn mímọ́, olódodo, lábẹ́ aṣọ mímọ́ yín ni ọkàn tí ó kún fún ìbàjẹ́ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àgàbàgebè àti ẹ̀ṣẹ̀ wà.

Matthew 23:28 in English

Matthew 23:28 · Berean Standard Bible

In the same way, on the outside you appear to be righteous, but on the inside you are full of hypocrisy and wickedness.

Context

26Ìwọ afọ́jú Farisi, tètè kọ́ fọ inú ago àti àwo, gbogbo ago náà yóò sì di mímọ́. 27“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ dàbí ibojì funfun tí ó dára ní wíwò, ṣùgbọ́n tí ó kún fún egungun ènìyàn àti fún ẹ̀gbin àti ìbàjẹ́. 28Ẹ̀yin gbìyànjú láti farahàn bí ènìyàn mímọ́, olódodo, lábẹ́ aṣọ mímọ́ yín ni ọkàn tí ó kún fún ìbàjẹ́ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àgàbàgebè àti ẹ̀ṣẹ̀ wà. 29“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè, nítorí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì tí í ṣe ibojì àwọn olódodo ní ọ̀ṣọ́. 30Ẹ̀yin sì wí pé, ‘Àwa ìbá wà ní àsìkò àwọn baba wa, àwa kì bá ní ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì’.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.