Matiu 23:21
Matthew 23:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti pé, ẹni tí ó bá fi tẹmpili búra, ó fi í búra àti ẹni tí ń gbé inú rẹ̀.
Matthew 23:21 in English
Matthew 23:21 · Berean Standard Bible
And he who swears by the temple swears by it and by the One who dwells in it.
Context
19Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú wọ̀nyí! Èwo ni ó pọ̀jù: ẹ̀bùn tí ó wà lórí pẹpẹ ni tàbí pẹpẹ fúnra rẹ̀ tí ó sọ ẹ̀bùn náà di mímọ́? 20Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fi pẹpẹ búra, ó fi í búra àti gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀. 21Àti pé, ẹni tí ó bá fi tẹmpili búra, ó fi í búra àti ẹni tí ń gbé inú rẹ̀. 22Àti pé, ẹni tí ó bá sì fi ọ̀run búra, ó fi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ búra. 23“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin ń gba ìdámẹ́wàá minti, dili àti kumini, ẹ̀yin sì ti fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú òfin sílẹ̀ láìṣe, ìdájọ́, àánú àti ìgbàgbọ́. Wọ̀nyí ni ó tọ́ tí ẹ̀yin ìbá ṣe, ẹ̀yin kò bá fi wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ láìṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.