Matiu 22:4
Matthew 22:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Lẹ́yìn náà ó tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí mo ti pè wí pé, mo ti ṣe àsè náà tán. A pa màlúù àti ẹran àbọ́pa mi, a ti ṣe ohun gbogbo tán, ẹ wa sí ibi àsè ìgbéyàwó.’
Matthew 22:4 in English
Matthew 22:4 · Berean Standard Bible
Again, he sent other servants and said, ‘Tell those who have been invited that I have prepared my dinner. My oxen and fattened cattle have been killed, and everything is ready. Come to the wedding banquet.’
Context
2“Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan ti ó múra àsè ìgbéyàwó ńlá fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. 3Ó rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ pe àwọn tí a ti pè tẹ́lẹ̀ sí ibi àsè ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ wá. 4“Lẹ́yìn náà ó tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí mo ti pè wí pé, mo ti ṣe àsè náà tán. A pa màlúù àti ẹran àbọ́pa mi, a ti ṣe ohun gbogbo tán, ẹ wa sí ibi àsè ìgbéyàwó.’ 5“Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó ránṣẹ́ lọ pè kò kà á si. Wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ, ọ̀kan sí ọ̀nà oko rẹ̀, òmíràn sí ibi òwò rẹ̀.” 6Àwọn ìyókù sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àbùkù sí wọn, wọ́n lù wọ́n pa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.