Matiu 22:22
Matthew 22:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.
Matthew 22:22 in English
Matthew 22:22 · Berean Standard Bible
And when they heard this, they were amazed. So they left Him and went away.
Context
20ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán ta ni èyí? Àkọlé tà sì ní?” 21Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Kesari ni.”
“Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Kesari fún Kesari, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” 22Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ. 23Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan náà, àwọn Sadusi tí wọ́n sọ pé kò si àjíǹde lẹ́yìn ikú tọ Jesu wá láti bi í ní ìbéèrè, 24wọ́n wí pé, “Olùkọ́, Mose wí fún wa pé, bí ọkùnrin kan bá kú ní àìlọ́mọ, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó sì bí ọmọ fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.