Native Bible

Matthew 21:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ìdàkejì, bí àwa bá sì sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, àwa bẹ̀rù ìjọ ènìyàn, nítorí gbogbo wọ́n ka Johanu sí wòlíì.’ ”

Matthew 21:26 in English

Matthew 21:26 · Berean Standard Bible

But if we say, ‘From men,’ we are afraid of the people, for they all regard John as a prophet.”

Context

24Jesu sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi yóò si bí yin léèrè ohun kan, bí ẹ̀yin bá lé sọ fún mi, nígbà náà èmi yóò sọ fún yín, àṣẹ tí Èmi fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí. 25Níbo ni ìtẹ̀bọmi Johanu ti wa? Láti ọ̀run wá ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn.” Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun yóò wí fún wa pé, ‘Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’ 26Ní ìdàkejì, bí àwa bá sì sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, àwa bẹ̀rù ìjọ ènìyàn, nítorí gbogbo wọ́n ka Johanu sí wòlíì.’ ” 27Nítorí náà wọ́n sì dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí èyí, èmi kò ní sọ àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín. 28“Kí ni ẹ rò nípa eléyìí? Ọkùnrin kan ti ó ní àwọn ọmọkùnrin méjì. Ó sọ fún èyí ẹ̀gbọ́n pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.