Native Bible

Matthew 20:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

pé, ‘Wákàtí kan péré ni àwọn tí a gbà kẹ́yìn fi ṣiṣẹ́, ìwọ sì san iye kan náà fún wọn àti àwa náà ti a fi gbogbo ọjọ́ ṣiṣẹ́ nínú oòrùn gangan.’

Matthew 20:12 in English

Matthew 20:12 · Berean Standard Bible

‘These men who were hired last worked only one hour,’ they said, ‘and you have made them equal to us who have borne the burden and the scorching heat of the day.’

Context

10Nígbà tí àwọn tí a gbà ṣiṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ fẹ́ gba owó tiwọn, èrò wọn ni pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan. 11Bí wọ́n ti ń gbà á, wọ́n ń kùn sí onílẹ̀ náà, 12pé, ‘Wákàtí kan péré ni àwọn tí a gbà kẹ́yìn fi ṣiṣẹ́, ìwọ sì san iye kan náà fún wọn àti àwa náà ti a fi gbogbo ọjọ́ ṣiṣẹ́ nínú oòrùn gangan.’ 13“Ṣùgbọ́n ó dá ọ̀kan nínú wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀rẹ́, kò sí aburú nínú nǹkan tí èmi ṣe sí yín. Kì í ha ṣe pé ẹ̀yin gbà láti ṣiṣẹ́ fún owó dínárì kan. 14Ó ní, gba èyí tí í ṣé tìrẹ, ki ó sì máa lọ. Èmi fẹ́ láti fún ẹni ìkẹyìn gẹ́gẹ́ bí mo ti fi fún ọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.