Native Bible

Matthew 2:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì wí fún un pé, “Dìde gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ padà sí ilẹ̀ Israẹli, nítorí àwọn tí ń wá ẹ̀mí ọmọ ọwọ́ náà láti pa ti kú.”

Matthew 2:20 in English

Matthew 2:20 · Berean Standard Bible

“Get up!” he said. “Take the Child and His mother and go to the land of Israel, for those seeking the Child’s life are now dead.”

Context

18“A gbọ́ ohùn kan ní Rama, ohùn réré ẹkún àti ọ̀fọ̀ ńlá, Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀. Ó kọ̀ láti gbìpẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.” 19Lẹ́yìn ikú Herodu, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu lójú àlá ní Ejibiti 20Ó sì wí fún un pé, “Dìde gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ padà sí ilẹ̀ Israẹli, nítorí àwọn tí ń wá ẹ̀mí ọmọ ọwọ́ náà láti pa ti kú.” 21Nítorí náà, o sì dìde, ó gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ó sì wá sí ilẹ̀ Israẹli. 22Ṣùgbọ́n nígbà tí ó gbọ́ pé Akelausi ni ó ń jẹ ọba ní Judea ní ipò Herodu baba rẹ̀, ó bẹ̀rù láti lọ sí ì bẹ̀. Nítorí tí Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún un ní ojú àlá, ó yí padà, ó sì gba ẹkùn Galili lọ,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.