Matiu 19:7
Matthew 19:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n bi í pé: “Kí ni ìdí tí Mose fi pàṣẹ pé, ọkùnrin kan lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nípa fífún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀?”
Matthew 19:7 in English
Matthew 19:7 · Berean Standard Bible
“Why then,” they asked, “did Moses order a man to give his wife a certificate of divorce and send her away?*”
Context
5Ó sì wí fún un pé, ‘Nítorí ìdí èyí ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.’ 6Wọn kì í túnṣe méjì mọ́, ṣùgbọ́n ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run bá ti so ṣọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà wọ́n.” 7Wọ́n bi í pé: “Kí ni ìdí tí Mose fi pàṣẹ pé, ọkùnrin kan lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nípa fífún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀?” 8Jesu dáhùn pé, “Nítorí líle àyà yín ni Mose ṣe gbà fún yín láti máa kọ aya yín sílẹ̀. Ṣùgbọ́n láti ìgbà àtètèkọ́ṣe wá, kò rí bẹ́ẹ̀. 9Mo sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, tí ó bá sì fẹ́ ẹlòmíràn, ó ṣe panṣágà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.