Matiu 19:18
Matthew 19:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?” Jesu dáhùn pé, “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn; ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà; ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké’,
Matthew 19:18 in English
Matthew 19:18 · Berean Standard Bible
“Which ones?” the man asked. Jesus answered, “‘Do not murder, do not commit adultery, do not steal, do not bear false witness,
Context
16Ẹnìkan sì wá ó bí Jesu pé, “Olùkọ́, ohun rere kí ni èmi yóò ṣe, kí èmi kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?” 17Jesu dá a lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe ẹni rere. Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́.” 18Ọkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?”
Jesu dáhùn pé, “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn; ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà; ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké’, 19bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. ‘Kí o sì fẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ” 20Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi ní láti ṣe?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.