Native Bible

Matthew 18:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Mo tún sọ èyí fún yín, bí ẹ̀yin méjì bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé yìí, nípa ohunkóhun tí ẹ béèrè, Baba mi ti ń bẹ ní ọ̀run yóò sì ṣe é fún yín.

Matthew 18:19 in English

Matthew 18:19 · Berean Standard Bible

Again, I tell you truly that if two of you on the earth agree about anything you ask for, it will be done for you by My Father in heaven.

Context

17Bí òun bá sì tún kọ̀ láti tẹ́tí sí wọn, nígbà náà sọ fún ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. Bí o bá kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọ́run, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ tàbí agbowó òde. 18“Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá dè ní ayé, ni a dè ní ọ̀run. Ohunkóhun ti ẹ̀yin bá sì ti tú ni ayé, á ò tú u ní ọ̀run. 19“Mo tún sọ èyí fún yín, bí ẹ̀yin méjì bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé yìí, nípa ohunkóhun tí ẹ béèrè, Baba mi ti ń bẹ ní ọ̀run yóò sì ṣe é fún yín. 20Nítorí níbi ti ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta bá kó ara jọ ni orúkọ mi, èmi yóò wà láàrín wọn níbẹ̀.” 21Nígbà náà ni Peteru wá sọ́dọ̀ Jesu, ó béèrè pé, “Olúwa, nígbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mi, tí èmi yóò sì dáríjì í? Tàbí ní ìgbà méje ni?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.