Matiu 18:10
Matthew 18:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ rí i pé ẹ kò fi ojú tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn kéékèèké wọ̀nyí. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, nígbà gbogbo ni ọ̀run ni àwọn angẹli ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.*
Matthew 18:10 in English
Matthew 18:10 · Berean Standard Bible
See that you do not look down on any of these little ones. For I tell you that their angels in heaven always see the face of My Father in heaven.*
Context
8Nítorí náà, bí ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ rẹ yóò bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀, gé e kúrò, kí o sì jù ú nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run ní akéwọ́ tàbí akésẹ̀ ju pé kí o ni ọwọ́ méjì àti ẹsẹ̀ méjì ki a sì sọ ọ́ sínú iná ayérayé. 9Bí ojú rẹ yóò bá sì mú kí o dẹ́ṣẹ̀, yọ ọ́ kúrò kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti lọ sínú ìyè pẹ̀lú ojú kan, ju pé kí o ní ojú méjì, kí a sì jù ọ́ sí iná ọ̀run àpáàdì. 10“Ẹ rí i pé ẹ kò fi ojú tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn kéékèèké wọ̀nyí. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, nígbà gbogbo ni ọ̀run ni àwọn angẹli ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.* 12“Kí ni ẹ̀yin rò? Bí ọkùnrin kan bá ni ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ẹyọ kan nínú wọn sì sọnù, ṣé òun kì yóò fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún ìyókù sílẹ̀ sórí òkè láti lọ wá ẹyọ kan tó nù náà bí? 13Ǹjẹ́ bí òun bá sì wá á rí i, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé inú rẹ̀ yóò dùn nítorí rẹ̀ ju àwọn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún tí kò nù lọ?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.