Matiu 17:16
Matthew 17:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo sì ti mú un tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè wò ó sàn.”
Matthew 17:16 in English
Matthew 17:16 · Berean Standard Bible
I brought him to Your disciples, but they could not heal him.”
Context
14Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ ìjọ ènìyàn, ọkùnrin kan tọ̀ Jesu wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí pé, 15“Olúwa, ṣàánú fún ọmọ mi, nítorí tí ó ní wárápá. Ó sì ń joró gidigidi, nígbà púpọ̀ ni ó máa ń ṣubú sínú iná tàbí sínú omi. 16Mo sì ti mú un tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè wò ó sàn.” 17Jesu sì dáhùn wí pé, “A! Ẹ̀yìn alágídí ọkàn àti aláìgbàgbọ́ ènìyàn, èmi yóò ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi ó sì ti fi ara dà á fún yín tó? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín yìí.” 18Nígbà náà ni Jesu bá ẹ̀mí èṣù tí ó ń bẹ nínú ọmọkùnrin náà wí, ó sì fi í sílẹ̀, à mú ọmọkùnrin náà láradá láti ìgbà náà lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.