Native Bible

Matthew 16:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóò sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nítorí mi, yóò rí i.

Matthew 16:25 in English

Matthew 16:25 · Berean Standard Bible

For whoever wants to save his life will lose it, but whoever loses his life for My sake will find it.

Context

23Jesu pa ojú dà, ó sì wí fún Peteru pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi; ìwọ kò ro ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, bí kò ṣe èyí ti ṣe ti ènìyàn.” 24Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. 25Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóò sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nítorí mi, yóò rí i. 26Èrè kí ni ó jẹ́ fún ènìyàn bí ó bá jèrè gbogbo ayé yìí, tí ó sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi dípò ẹ̀mí rẹ̀? 27Nítorí Ọmọ Ènìyàn yóò wá nínú ògo baba rẹ pẹ̀lú àwọn angẹli rẹ̀, nígbà náà ni yóò sì san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.