Native Bible

Matthew 16:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn Farisi àti àwọn Sadusi wá láti dán Jesu wò. Wọ́n ní kí ó fi àmì ńlá kan hàn àwọn ní ojú ọ̀run.

Matthew 16:1 in English

Matthew 16:1 · Berean Standard Bible

Then the Pharisees and Sadducees came and tested Jesus by asking Him to show them a sign from heaven.

Context

1Àwọn Farisi àti àwọn Sadusi wá láti dán Jesu wò. Wọ́n ní kí ó fi àmì ńlá kan hàn àwọn ní ojú ọ̀run. 2Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ó bá di àṣálẹ́, ẹ ó sọ pé, ‘Ìbá dára kí ojú ọ̀run pọ́n.’ 3Ní òwúrọ̀, ‘Ẹ̀yin yóò wí pé ọjọ́ kì yóò dára lónìí, nítorí ti ojú ọ̀run pọ́n, ó sì ṣú dẹ̀dẹ̀,’ ẹ̀yin àgàbàgebè, ẹ̀yin le sọ àmì ojú ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò le mọ àmì àwọn àkókò wọ̀nyí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.