Native Bible

Matthew 15:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì dá a lóhùn pé, “Níbo ni àwa yóò ti rí oúnjẹ ní ijù níhìn-ín yìí láti fi bọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí?”

Matthew 15:33 in English

Matthew 15:33 · Berean Standard Bible

The disciples replied, “Where in this desolate place could we find enough bread to feed such a large crowd?”

Context

31Ẹnu ya ọ̀pọ̀ ènìyàn nígbà tí wọ́n rí àwọn odi tó ń sọ̀rọ̀, amúnkùn ún tó di alára pípé, arọ tí ó ń rìn àti àwọn afọ́jú tí ó ríran. Wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọ́run Israẹli. 32Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó wí pé, “Àánú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí; nítorí wọ́n ti wà níhìn-ín pẹ̀lú mi fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko báyìí. Wọn kò sì tún ní oúnjẹ mọ́. Èmi kò fẹ́ kí wọn padà lébi, nítorí òyì lè kọ́ wọn lójú ọ̀nà.” 33Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì dá a lóhùn pé, “Níbo ni àwa yóò ti rí oúnjẹ ní ijù níhìn-ín yìí láti fi bọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí?” 34Jesu sì béèrè pé, “Ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ní?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Àwa ní ìṣù àkàrà méje pẹ̀lú àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀.” 35Jesu sì sọ fún gbogbo ènìyàn kí wọn jókòó lórí ilẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.