Matiu 15:13
Matthew 15:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi ti ń bẹ ni ọ̀run kò bá gbìn ni á ó fàtu tigbòǹgbò tigbòǹgbò,
Matthew 15:13 in English
Matthew 15:13 · Berean Standard Bible
But Jesus replied, “Every plant that My heavenly Father has not planted will be pulled up by its roots.
Context
11Ènìyàn kò di aláìmọ́ nípa ohun tí ó wọ ẹnu ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti ẹnu jáde wá ni ó sọ ní di aláìmọ́.” 12Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún un pé, “Ǹjẹ́ ìwọ mọ̀ pé inú bí àwọn Farisi lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó sọ yìí?” 13Jesu dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi ti ń bẹ ni ọ̀run kò bá gbìn ni á ó fàtu tigbòǹgbò tigbòǹgbò, 14ẹ fi wọ́n sílẹ̀; afọ́jú tí ń fi ọ̀nà han afọ́jú ni wọ́n. Bí afọ́jú bá sì ń fi ọ̀nà han afọ́jú, àwọn méjèèjì ni yóò jìn sí kòtò.” 15Peteru wí, “Ṣe àlàyé òwe yìí fún wa.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.