Native Bible

Matthew 13:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn gòkè, oòrùn gbígbóná jó wọn, gbogbo wọn sì rọ, wọ́n kú nítorí wọn kò ni gbòǹgbò.

Matthew 13:6 in English

Matthew 13:6 · Berean Standard Bible

But when the sun rose, the seedlings were scorched, and they withered because they had no root.

Context

4Bí ó sì ti gbin irúgbìn náà, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì jẹ ẹ́. 5Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ orí àpáta, níbi ti kò sí erùpẹ̀ púpọ̀. Àwọn irúgbìn náà sì dàgbàsókè kíákíá, nítorí erùpẹ̀ kò pọ̀ lórí wọn. 6Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn gòkè, oòrùn gbígbóná jó wọn, gbogbo wọn sì rọ, wọ́n kú nítorí wọn kò ni gbòǹgbò. 7Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sí àárín ẹ̀gún, ẹ̀gún sì dàgbà, ó sì fún wọn pa. 8Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́rùn-ún, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ti ó gbìn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.