Matiu 12:45
Matthew 12:45 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn pẹ̀lú ara rẹ̀, tí ó burú ju òun fúnra rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn yóò sì wá sí inú rẹ̀, wọn yóò máa gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà a sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí fún ìran búburú yìí pẹ̀lú.”
Matthew 12:45 in English
Matthew 12:45 · Berean Standard Bible
Then it goes and brings with it seven other spirits more wicked than itself, and they go in and dwell there; and the final plight of that man is worse than the first. So will it be with this wicked generation.”
Context
43“Nígbà tí ẹ̀mí búburú kan bá jáde lára ènìyàn, a máa rìn ní ibi gbígbẹ́, a máa wá ibi ìsinmi, kò sì ní rí i. 44Nígbà náà ni ẹ̀mí náà yóò wí pé, ‘Èmi yóò padà sí ara ọkùnrin tí èmí ti wá.’ Bí ó bá sì padà, tí ó sì bá ọkàn ọkùnrin náà ni òfìfo, a gbà á mọ́, a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́. 45Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn pẹ̀lú ara rẹ̀, tí ó burú ju òun fúnra rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn yóò sì wá sí inú rẹ̀, wọn yóò máa gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà a sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí fún ìran búburú yìí pẹ̀lú.” 46Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, wò ó, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. 47Nígbà náà ni ẹnìkan wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró dè ọ́ lóde wọ́n ń fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.