Matiu 12:39
Matthew 12:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì dá wọn lóhùn wí pé, “Ìran búburú àti ìran panṣágà ń béèrè àmì; ṣùgbọ́n kò sí àmì tí a ó fi fún un, bí kò ṣe àmì Jona wòlíì.
Matthew 12:39 in English
Matthew 12:39 · Berean Standard Bible
Jesus replied, “A wicked and adulterous generation demands a sign, but none will be given it except the sign of the prophet Jonah.
Context
37Nítorí nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín ni a fi dá yin láre, nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín sì ni a ó fi dá yin lẹ́bi.” 38Nígbà náà ni, díẹ̀ nínú àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin wí fún pé “Olùkọ́, àwa fẹ́ rí iṣẹ́ àmì kan lọ́dọ̀ rẹ̀”. 39Ó sì dá wọn lóhùn wí pé, “Ìran búburú àti ìran panṣágà ń béèrè àmì; ṣùgbọ́n kò sí àmì tí a ó fi fún un, bí kò ṣe àmì Jona wòlíì. 40Bí Jona ti gbé inú ẹja ńlá fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí Ọmọ Ènìyàn yóò gbé ní inú ilẹ̀ fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta. 41Àwọn ará Ninefe yóò dìde pẹ̀lú ìran yìí ní ọjọ́ ìdájọ́. Wọn yóò sì dá a lẹ́bi. Nítorí pé wọ́n ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jona. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀jù Jona wà níhìn-ín yìí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.