Matiu 12:25
Matthew 12:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesu tí ó mọ èrò wọn, ó wí fún wọn pé, “Ìjọbakíjọba tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ yóò parun, ìlúkílùú tàbí ilékílé tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ kì yóò dúró.
Matthew 12:25 in English
Matthew 12:25 · Berean Standard Bible
Knowing their thoughts, Jesus said to them, “Every kingdom divided against itself will be laid waste, and every city or household divided against itself will not stand.
Context
23Ẹnu sì ya gbogbo àwọn ènìyàn. Wọ́n wí pé, “Èyí ha lè jẹ́ Ọmọ Dafidi bí?” 24Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Nípa Beelsebulu nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.” 25Jesu tí ó mọ èrò wọn, ó wí fún wọn pé, “Ìjọbakíjọba tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ yóò parun, ìlúkílùú tàbí ilékílé tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ kì yóò dúró. 26Bí èṣù bá sì ń lé èṣù jáde, a jẹ́ wí pé, ó ń yapa sí ara rẹ̀. Ìjọba rẹ yóò ha ṣe le dúró? 27Àti pé, bi èmi bá ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípa Beelsebulu, nípa ta ni àwọn ènìyàn yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà ni wọn yóò ṣe má ṣe ìdájọ́ yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.