Native Bible

Matthew 12:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Jesu sì mọ̀, ó yẹra kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá.

Matthew 12:15 in English

Matthew 12:15 · Berean Standard Bible

Aware of this, Jesus withdrew from that place. Large crowds followed Him, and He healed them all,

Context

13Nígbà náà, ó sì wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ,” bí òun sì ti nà án, ọwọ́ rẹ̀ sì bọ̀ sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ èkejì. 14Síbẹ̀ àwọn Farisi jáde lọ pe ìpàdé láti dìtẹ̀ mú un àti bí wọn yóò ṣe pa Jesu. 15Nígbà tí Jesu sì mọ̀, ó yẹra kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá. 16Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n kí ó má ṣe fi òun hàn. 17Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ èyí tí wòlíì Isaiah sọ nípa rẹ̀ pé,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.