Native Bible

Matthew 11:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọmọ Ènìyàn wá bá a yín jẹun, ó sì bá yin mu, wọ́n wí pé, ‘Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtí; ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’ Ṣùgbọ́n a dá ọgbọ́n láre nípa ìṣe rẹ̀.”

Matthew 11:19 in English

Matthew 11:19 · Berean Standard Bible

The Son of Man came eating and drinking, and they say, ‘Look at this glutton and drunkard, a friend of tax collectors and sinners!’ But wisdom is vindicated by her actions.”

Context

17“ ‘Àwa ń fun fèrè fún yín, ẹ̀yin kò jó; àwa kọrin ọ̀fọ̀ ẹ̀yin kò káàánú.’ 18Nítorí Johanu wá kò bá a yín jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò mu, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù.’ 19Ọmọ Ènìyàn wá bá a yín jẹun, ó sì bá yin mu, wọ́n wí pé, ‘Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtí; ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’ Ṣùgbọ́n a dá ọgbọ́n láre nípa ìṣe rẹ̀.” 20Nígbà náà ni Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìlú tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ wí, nítorí wọn kò ronúpìwàdà. 21Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Korasini, ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú yín ní a ṣe ni Tire àti Sidoni, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà ti pẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.