Malaki 3:8
Malachi 3:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run ni olè bí? Síbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí ní olè. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe jà ọ́ ní olè?’ “Nípa ìdámẹ́wàá àti ọrẹ.
Malachi 3:8 in English
Malachi 3:8 · Berean Standard Bible
Will a man rob God? Yet you are robbing Me! But you ask, ‘How do we rob You?’ In tithes and offerings.
Context
6“Èmi Olúwa kò yípadà. Nítorí náà ni a kò ṣe run ẹ̀yin ọmọ Jakọbu. 7Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá yín wá ni ẹ̀yin tilẹ̀ ti kọ ẹ̀yìn sí ìlànà mi, tí ẹ kò sì pa wọ́n mọ́. Ẹ padà wá sí ọ̀dọ̀ mi, Èmi yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa yóò ṣe padà?’ 8“Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run ni olè bí? Síbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí ní olè.
“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe jà ọ́ ní olè?’
“Nípa ìdámẹ́wàá àti ọrẹ. 9Ríré ni a ó fi yín ré: gbogbo orílẹ̀-èdè yìí, nítorí ẹ̀yin ti jà mi lólè. 10Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ bá à lè wà ní ilé mi, ẹ fi èyí dán mi wò,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “kí ẹ sì wò bí èmi kò bá ní sí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yin, kí èmi sì tú ìbùkún àkúnwọ́sílẹ̀ jáde fún yín, tó bẹ́ẹ̀ tí kì yóò sì ààyè láti gbà á.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.