Native Bible

Malachi 3:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

nígbà náà ni ọrẹ Juda àti ti Jerusalẹmu yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ àtijọ́, àti gẹ́gẹ́ bí ọdún ìgbàanì.

Malachi 3:4 in English

Malachi 3:4 · Berean Standard Bible

Then the offerings of Judah and Jerusalem will please the LORD, as in days of old and years gone by.

Context

2Ṣùgbọ́n ta ni o lè fi ara da ọjọ́ dídé rẹ̀? Ta ni yóò sì dúró nígbà tí ó bá fi ara hàn? Nítorí òun yóò dàbí iná ẹni tí ń da fàdákà àti bi ọṣẹ alágbàfọ̀. 3Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà; yóò wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, yóò sì tún wọn dàbí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún Olúwa, 4nígbà náà ni ọrẹ Juda àti ti Jerusalẹmu yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ àtijọ́, àti gẹ́gẹ́ bí ọdún ìgbàanì. 5“Èmi ó sì súnmọ́ yin fún ìdájọ́. Èmi yóò sì yára ṣe ẹlẹ́rìí sí àwọn oṣó, sí àwọn panṣágà, sí àwọn abúra èké, àti àwọn tí ó fi ọ̀yà alágbàṣe pọn wọn lójú, àti àwọn tí ó ni àwọn opó àti àwọn aláìní baba lára, àti sí ẹni tí kò jẹ́ kí àjèjì rí ìdájọ́ òdodo gbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 6“Èmi Olúwa kò yípadà. Nítorí náà ni a kò ṣe run ẹ̀yin ọmọ Jakọbu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.