Native Bible

Malachi 3:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Wọn yóò sì jẹ́ tèmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “ni ọjọ́ náà, tí èmi ó dá; èmi yóò sì da wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí máa ń dá ọmọ rẹ̀ tí yóò sìn ín sí.

Malachi 3:17 in English

Malachi 3:17 · Berean Standard Bible

“They will be Mine,” says the LORD of Hosts, “on the day when I prepare My treasured possession. And I will spare them as a man spares his own son who serves him.

Context

15Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí àwa pé agbéraga ni alábùkún fún. Ní òtítọ́ ni àwọn ti ń ṣe búburú ń gbèrú sí i, kódà àwọn ti ó dán Ọlọ́run wò ni a dá sí.’ ” 16Nígbà náà ni àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa ń ba ara wọn sọ̀rọ̀, Olúwa sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́. A sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí o bẹ̀rù Olúwa, tiwọn sì bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀. 17“Wọn yóò sì jẹ́ tèmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “ni ọjọ́ náà, tí èmi ó dá; èmi yóò sì da wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí máa ń dá ọmọ rẹ̀ tí yóò sìn ín sí. 18Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìyàtọ̀, ìyàtọ̀ láàrín olódodo àti ẹni búburú, láàrín ẹni tí ń sìn Ọlọ́run, àti ẹni tí kò sìn ín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.