Malaki 3:12
Malachi 3:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nígbà náà ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì pè yín ni alábùkún fún, nítorí tiyín yóò jẹ́ ilẹ̀ tí ó wu ni,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Malachi 3:12 in English
Malachi 3:12 · Berean Standard Bible
“Then all the nations will call you blessed, for you will be a land of delight,” says the LORD of Hosts.
Context
10Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ bá à lè wà ní ilé mi, ẹ fi èyí dán mi wò,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “kí ẹ sì wò bí èmi kò bá ní sí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yin, kí èmi sì tú ìbùkún àkúnwọ́sílẹ̀ jáde fún yín, tó bẹ́ẹ̀ tí kì yóò sì ààyè láti gbà á. 11Èmi yóò sì bá kòkòrò ajẹnirun wí nítorí yín, òun kò sì ni run èso ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni àjàrà inú oko yín kò ní rẹ̀ dànù,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 12“Nígbà náà ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì pè yín ni alábùkún fún, nítorí tiyín yóò jẹ́ ilẹ̀ tí ó wu ni,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 13“Ẹ̀yin ti sọ ọ̀rọ̀ líle sí mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Síbẹ̀ ẹ̀yin béèrè pé, ‘Ọ̀rọ̀ kín ni àwa sọ sí ọ?’ 14“Ẹ̀yin ti wí pé, ‘Asán ni láti sin Ọlọ́run. Kí ni àwa jẹ ní èrè, nígbà tí àwa ti pa ìlànà rẹ mọ́, tí àwa sì ń rìn kiri bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ní iwájú Olúwa àwọn ọmọ-ogun?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.