Malaki 2:8
Malachi 2:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yapa kúrò ní ọ̀nà náà; ẹ̀yin sì ti fi ìkọ́ni yín mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀; ẹ̀yin ti ba májẹ̀mú tí mo da pẹ̀lú Lefi jẹ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Malachi 2:8 in English
Malachi 2:8 · Berean Standard Bible
But you have departed from the way, and your instruction has caused many to stumble. You have violated the covenant of Levi,” says the LORD of Hosts.
Context
6Òfin òtítọ́ wà ni ẹnu rẹ̀, a kò sì rí irọ́ ni ètè rẹ̀: ó ba mi rìn ní àlàáfíà àti ni ìdúró ṣinṣin, ó sì yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. 7“Nítorí ètè àlùfáà ní òye láti máa pa ìmọ̀ mọ́, kí àwọn ènìyàn lè máa wá ìtọ́ni ni ẹnu rẹ̀: nítorí òun ni ìránṣẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 8Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yapa kúrò ní ọ̀nà náà; ẹ̀yin sì ti fi ìkọ́ni yín mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀; ẹ̀yin ti ba májẹ̀mú tí mo da pẹ̀lú Lefi jẹ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 9“Nítorí náà ni èmi pẹ̀lú ṣe sọ yín di ẹ̀gàn, àti ẹni àìkàsí níwájú gbogbo ènìyàn, nítorí ẹ̀yin kò tẹ̀lé ọ̀nà mi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń ṣe ojúsàájú nínú òfin.” 10Baba kan náà kí gbogbo wa ha ní? Ọlọ́run kan náà kọ́ ni ó dá wa bí? Nítorí kín ni àwa ha ṣe sọ májẹ̀mú àwọn baba wa di aláìmọ nípa híhu ìwà àrékérekè olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.