Native Bible

Malachi 2:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé, èmi ni ó ti rán òfin yìí sí yín, kí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Lefi lè tẹ̀síwájú,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

Malachi 2:4 in English

Malachi 2:4 · Berean Standard Bible

Then you will know that I have sent you this commandment so that My covenant with Levi may continue,” says the LORD of Hosts.

Context

2Bí ẹ̀yin kò bá ni gbọ́, bí ẹ̀yin kò bá ní fi í sí àyà láti fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí; èmi yóò sì ran ègún sí orí yín, èmi yóò sì fi ìbùkún yín ré. Nítòótọ́ mó ti fi ré ná, nítorí pé, ẹ̀yin kò fi sí ọkàn yín láti bu ọlá fún mi. 3“Nítorí tiyín èmí yóò ba àwọn ọmọ yín wí, èmi ó sì fi ìgbẹ́ rẹ́ yín lójú, àní àwọn ìgbẹ́ ọrẹ ọwọ́ yín wọ̀nyí, a ó sì kó yín lọ pẹ̀lú rẹ̀. 4Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé, èmi ni ó ti rán òfin yìí sí yín, kí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Lefi lè tẹ̀síwájú,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 5“Májẹ̀mú mi wà pẹ̀lú rẹ̀, májẹ̀mú ti ìyè àti àlàáfíà wà pẹ̀lú rẹ̀; mo sì fi wọn fún un, nítorí bíbẹ̀rù tí ó bẹ̀rù mi, tí ẹ̀rù orúkọ mi sì bà á. 6Òfin òtítọ́ wà ni ẹnu rẹ̀, a kò sì rí irọ́ ni ètè rẹ̀: ó ba mi rìn ní àlàáfíà àti ni ìdúró ṣinṣin, ó sì yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.