Native Bible

Luke 9:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Sì kíyèsi i, ẹ̀mí èṣù a máa mú un, a sì máa kígbe lójijì; a sì máa nà án tàntàn títí yóò fi yọ ìfófó lẹ́nu, a máa pa á lára, kì í tilẹ̀ ń fẹ́ fi í sílẹ̀ lọ.

Luke 9:39 in English

Luke 9:39 · Berean Standard Bible

A spirit keeps seizing him, and he screams abruptly. It throws him into convulsions so that he foams at the mouth. It keeps mauling him and rarely departs from him.

Context

37Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kejì, nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wá pàdé rẹ̀. 38Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan nínú ìjọ ènìyàn kígbe sókè pé, “Olùkọ́ mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọ mi: nítorí ọmọ mi kan ṣoṣo náà ni. 39Sì kíyèsi i, ẹ̀mí èṣù a máa mú un, a sì máa kígbe lójijì; a sì máa nà án tàntàn títí yóò fi yọ ìfófó lẹ́nu, a máa pa á lára, kì í tilẹ̀ ń fẹ́ fi í sílẹ̀ lọ. 40Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde: wọn kò sì lè ṣe é.” 41Jesu sì dáhùn pé, “Ìran aláìgbàgbọ́ àti àrékérekè, èmi ó ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti ṣe sùúrù fún yín pẹ́ tó? Fa ọmọ rẹ wá níhìn-ín yìí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.