Luku 9:30
Luke 9:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sì kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì, Mose àti Elijah, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀,
Luke 9:30 in English
Luke 9:30 · Berean Standard Bible
Suddenly two men, Moses and Elijah, began talking with Jesus.
Context
28Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Peteru àti Johanu àti Jakọbu, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà. 29Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbòò, 30Sì kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì, Mose àti Elijah, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀, 31tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerusalẹmu. 32Ṣùgbọ́n ojú Peteru àti ti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wúwo fún oorun. Nígbà tí wọ́n sì tají, wọ́n rí ògo rẹ̀, àti ti àwọn ọkùnrin méjèèjì tí ó bá a dúró.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.