Native Bible

Luke 9:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là.

Luke 9:24 in English

Luke 9:24 · Berean Standard Bible

For whoever wants to save his life will lose it, but whoever loses his life for My sake will save it.

Context

22Ó sì wí pé, “Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà, olórí àlùfáà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta a ó sì jí i dìde.” 23Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. 24Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là. 25Nítorí pé èrè kín ni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó fi ṣòfò. 26Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni Ọmọ Ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn angẹli mímọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.