Native Bible

Luke 8:48 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá, máa lọ ní Àlàáfíà.”

Luke 8:48 in English

Luke 8:48 · Berean Standard Bible

“Daughter,” said Jesus, “your faith has healed you. Go in peace.”

Context

46Jesu sì wí pé, “Ẹnìkan fi ọwọ́ kàn mí: nítorí tí èmí mọ̀ pé, àṣẹ jáde lára mi.” 47Nígbà tí obìnrin náà sì mọ̀ pé òun kò fi ara sin, ó wárìrì, ó wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ fún un lójú àwọn ènìyàn gbogbo nítorí ohun tí ó ṣe, tí òun fi fi ọwọ́ kàn án, àti bí a ti mú òun láradá lójúkan náà. 48Ó sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá, máa lọ ní Àlàáfíà.” 49Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lẹ́nu, ẹnìkan ti ilé olórí Sinagọgu wá, ó wí fún un pé, “Ọmọbìnrin rẹ kú; má yọ olùkọ́ni lẹ́nu mọ́.” 50Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́, ó dá a lóhùn, pé, “Má bẹ̀rù: sá gbàgbọ́ nìkan, a ó sì mú un láradá.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.