Luku 8:33
Luke 8:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ sì tú ka, wọ́n sí súré rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ sì bèbè odò bọ́ sínú adágún náà, wọ́n sì rì sínú rẹ̀.
Luke 8:33 in English
Luke 8:33 · Berean Standard Bible
Then the demons came out of the man and went into the pigs, and the herd rushed down the steep bank into the lake and was drowned.
Context
31Wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe rán wọn lọ sínú ọ̀gbun. 32Agbo ẹlẹ́dẹ̀ púpọ̀ sì ń bẹ níbẹ̀ tí ń jẹ lórí òkè: wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí àwọn wọ inú wọn lọ. Ó sì gba fún wọn. 33Nígbà tí àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ sì tú ka, wọ́n sí súré rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ sì bèbè odò bọ́ sínú adágún náà, wọ́n sì rì sínú rẹ̀. 34Nígbà tí àwọn tí n bọ́ wọn rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá, wọ́n sì lọ, wọ́n sì ròyìn ní ìlú àti ní ilẹ̀ náà. 35Nígbà náà ni wọ́n jáde lọ wo ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sì tọ Jesu wá, wọ́n sì rí ọkùnrin náà, lára ẹni tí àwọn ẹ̀mí èṣù ti jáde lọ, ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì bọ́ sí ipò: ẹ̀rù sì bà wọ́n.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.