Native Bible

Luke 8:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ó sì sọ̀kalẹ̀, ọkùnrin kan pàdé rẹ̀ lẹ́yìn ìlú náà, tí ó ti ní àwọn ẹ̀mí èṣù fún ìgbà pípẹ́, tí kì í wọ aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í jókòó ní ilé kan, bí kò ṣe ní ibojì.

Luke 8:27 in English

Luke 8:27 · Berean Standard Bible

When Jesus stepped ashore, He was met by a demon-possessed man from the town. For a long time this man had not worn clothing or lived in a house, but he stayed in the tombs.

Context

25Ó sì wí fún wọn pé, “Ìgbàgbọ́ yín dà?” Bí ẹ̀rù ti ń ba gbogbo wọn, tí hà sì ń ṣe wọ́n, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, nítorí ó bá ìjì líle àti ríru omi wí, wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀?” 26Wọ́n sì gúnlẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Gadara, tí ó kọjú sí Galili. 27Nígbà tí ó sì sọ̀kalẹ̀, ọkùnrin kan pàdé rẹ̀ lẹ́yìn ìlú náà, tí ó ti ní àwọn ẹ̀mí èṣù fún ìgbà pípẹ́, tí kì í wọ aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í jókòó ní ilé kan, bí kò ṣe ní ibojì. 28Nígbà tí ó rí Jesu, ó ké, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí lóhùn rara, pé, “Kí ni mo ní í ṣe pẹ̀lú rẹ, Jesu, ìwọ Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Èmi bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.” 29(Nítorí tí ó ti wí fún ẹ̀mí àìmọ́ náà pé, kí ó jáde kúrò lára ọkùnrin náà. Nígbàkígbà ni ó ń mú un: wọn a sì fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é; a sì ja gbogbo ìdè náà, ẹ̀mí èṣù náà a sì darí rẹ̀ sí ijù).

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.