Luku 7:6
Luke 7:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesu sì ń bá wọn lọ. Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu, nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi.
Luke 7:6 in English
Luke 7:6 · Berean Standard Bible
So Jesus went with them. But when He was not far from the house, the centurion sent friends with the message: “Lord, do not trouble Yourself, for I am not worthy to have You come under my roof.
Context
4Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún. 5Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, ó sì ti kọ́ Sinagọgu kan fún wa.” 6Jesu sì ń bá wọn lọ.
Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu, nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi. 7Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá, ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. 8Nítorí èmi náà pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí abẹ́ àṣẹ, tí ó ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi, mo sì wí fún ọ̀kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ; àti fún òmíràn pé, ‘Wá,’ a sì wá; àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.