Luku 7:42
Luke 7:42 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríjì àwọn méjèèjì. Wí nínú àwọn méjèèjì, ta ni yóò fẹ́ ẹ jù?”
Luke 7:42 in English
Luke 7:42 · Berean Standard Bible
When they were unable to repay him, he forgave both of them. Which one, then, will love him more?”
Context
40Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “Simoni, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.”
Ó sì dáhùn pé, “Olùkọ́ máa wí.” 41“Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbèsè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta. 42Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríjì àwọn méjèèjì. Wí nínú àwọn méjèèjì, ta ni yóò fẹ́ ẹ jù?” 43Simoni dáhùn wí pé, “Mo ṣe bí ẹni tí ó dáríjì jù ni.”
Jesu wí fún un pé, “Ìwọ ti dájọ́ náà dáradára.” 44Ó sì yípadà sí obìnrin náà, ó wí fún Simoni pé, “Wo obìnrin yìí? Èmi wọ ilé rẹ, ìwọ kò fi omi wẹ ẹsẹ̀ fún mi: ṣùgbọ́n, omijé rẹ̀ ni ó fi ń rọ̀jò sí mi lẹ́sẹ̀ irun orí ni ó fi ń nù wọ́n nù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.