Luku 7:39
Luke 7:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Farisi tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”
Luke 7:39 in English
Luke 7:39 · Berean Standard Bible
When the Pharisee who had invited Jesus saw this, he said to himself, “If this man were a prophet, He would know who this is and what kind of woman is touching Him—for she is a sinner!”
Context
37Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà ní ìlú náà, ẹni tí i ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀, nígbà tí ó mọ̀ pé Jesu jókòó, ó ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ṣágo kékeré alabasita òróró ìkunra wá, 38Ó sì dúró tì í lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, ó ń sọkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i fi omijé wẹ̀ ẹ́ ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ nù ún nù, ó sì ń fi ẹnu kò ó ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi òróró kùn wọ́n. 39Nígbà tí Farisi tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.” 40Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “Simoni, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.”
Ó sì dáhùn pé, “Olùkọ́ máa wí.” 41“Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbèsè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.