Luku 7:32
Luke 7:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé, “ ‘Àwa fọn fèrè fún yín, ẹ̀yin kò jó, àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín, ẹ̀yin kò sọkún!’
Luke 7:32 in English
Luke 7:32 · Berean Standard Bible
They are like children sitting in the marketplace and calling out to one another: ‘We played the flute for you, and you did not dance; we sang a dirge, and you did not weep.’
Context
30Ṣùgbọ́n àwọn Farisi àti àwọn amòfin kọ ète Ọlọ́run fún ara wọn, a kò bamitiisi wọn lọ́dọ̀ rẹ̀.) 31Jesu sì wí pé, “Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé? Kí ni wọ́n sì jọ? 32Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé,
“ ‘Àwa fọn fèrè fún yín,
ẹ̀yin kò jó, àwa sì ṣọ̀fọ̀ fún yín,
ẹ̀yin kò sọkún!’ 33Nítorí Johanu Onítẹ̀bọmi wá, kò jẹ àkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu ọtí wáìnì, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù?’ 34Ọmọ ènìyàn dé, ó ń jẹ, ó sì ń mu, ẹ̀yin sì wí pé, ‘Wò ó, ọ̀jẹun, àti ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀!’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.