Luku 7:12
Luke 7:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsi i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
Luke 7:12 in English
Luke 7:12 · Berean Standard Bible
As He approached the town gate, He saw a dead man being carried out, the only son of his mother, and she was a widow. And a large crowd from the town was with her.
Context
10Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ ọ̀dọ̀ náà tí ń ṣàìsàn, ara rẹ̀ ti dá. 11Ní ọjọ́ kejì, ó lọ sí ìlú kan tí a ń pè ní Naini, àwọn púpọ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń bá a lọ àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn. 12Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsi i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 13Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, “Má sọkún mọ́.” 14Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ pósí náà: àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́. Ó sì wí pé, “Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, dìde!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.