Luku 6:8
Luke 6:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ó mọ èrò inú wọn, ó sì wí fún ọkùnrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde, kí o sì dúró láàrín.” Ó sì dìde dúró.
Luke 6:8 in English
Luke 6:8 · Berean Standard Bible
But Jesus knew their thoughts and said to the man with the withered hand, “Get up and stand among us.” So he got up and stood there.
Context
6Ní ọjọ́ ìsinmi mìíràn, ó wọ inú Sinagọgu lọ, ó sì ń kọ́ni, ọkùnrin kan sì ń bẹ níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ. 7Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi ń ṣọ́ ọ, bóyá yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi; kí wọn lè rí ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kàn án. 8Ṣùgbọ́n ó mọ èrò inú wọn, ó sì wí fún ọkùnrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde, kí o sì dúró láàrín.” Ó sì dìde dúró. 9Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Èmi bi yín léèrè, Ó ha tọ́ láti máa ṣe rere ni ọjọ́ ìsinmi, tàbí láti máa ṣe búburú? Láti gba ọkàn là, tàbí láti pa á run?” 10Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká, ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀: ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ̀ sípò gẹ́gẹ́ bí èkejì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.