Native Bible

Luke 6:45 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ènìyàn rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá; àti ènìyàn búburú láti inú ìṣúra búburú ọkàn rẹ̀ ní í mú ohun búburú jáde wá: nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkàn ní ẹnu ti máa sọ jáde.

Luke 6:45 in English

Luke 6:45 · Berean Standard Bible

The good man brings good things out of the good treasure of his heart, and the evil man brings evil things out of the evil treasure of his heart. For out of the overflow of the heart, the mouth speaks.

Context

43“Nítorí igi rere kì í so èso búburú; bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kì í so èso rere. 44Olúkúlùkù igi ni a ń fi èso rẹ̀ mọ̀ ọn; nítorí lórí ẹ̀gún òṣùṣú, ènìyàn kì í ká èso ọ̀pọ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ ni lórí ẹ̀gún ọ̀gàn a kì í ká èso àjàrà. 45Ènìyàn rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá; àti ènìyàn búburú láti inú ìṣúra búburú ọkàn rẹ̀ ní í mú ohun búburú jáde wá: nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkàn ní ẹnu ti máa sọ jáde. 46“Nítorí náà, èéṣe tí ẹ̀yin ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ tí ẹ̀yin kò sì ṣe ohun tí mo wí? 47Ẹnikẹ́ni tí ó tọ̀ mí wá, tí ó sì ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì ń ṣe é, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.