Luku 6:40
Luke 6:40 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ: ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí a bá kọ dáradára, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀.
Luke 6:40 in English
Luke 6:40 · Berean Standard Bible
A disciple is not above his teacher, but everyone who is fully trained will be like his teacher.
Context
38Ẹ fi fún ni, a ó sì fi fún yín; òsùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ́n si àyà yín: nítorí òsùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ́n, òun ni a ó padà fi wọ́n fún yín.” 39Ó sì pa òwe kan fún wọn wí pé, “Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí? Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí? 40Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ: ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí a bá kọ dáradára, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀. 41“Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? 42Tàbí ìwọ ó ti ṣe lè wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Arákùnrin, jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ lójú rẹ,’ nígbà tí ìwọ tìkára rẹ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ lójú rẹ? Ìwọ àgàbàgebè, kọ́kọ́ yọ ìtí igi jáde kúrò lójú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ ó sì tó ríran gbangba láti yọ èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ kúrò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.