Native Bible

Luke 6:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú.

Luke 6:36 in English

Luke 6:36 · Berean Standard Bible

Be merciful, just as your Father is merciful.

Context

34Bí ẹ̀yin bá fi fún ẹni tí ẹ̀yin ń retí láti rí gbà padà, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú ń yá ẹlẹ́ṣẹ̀, kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà. 35Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú. 36Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú. 37“Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́: ẹ má ṣe dá ni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi: ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín. 38Ẹ fi fún ni, a ó sì fi fún yín; òsùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ́n si àyà yín: nítorí òsùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ́n, òun ni a ó padà fi wọ́n fún yín.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.