Luku 5:37
Luke 5:37 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti wí pé, kò sí ẹni tí ó lè dá ọtí wáìnì tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ, tí ó bá ṣe èyí, wáìnì tuntun yóò fa awọ náà ya, wáìnì náà yóò dànù, awọ náà a sì bàjẹ́.
Luke 5:37 in English
Luke 5:37 · Berean Standard Bible
And no one pours new wine into old wineskins. If he does, the new wine will burst the skins, the wine will spill, and the wineskins will be ruined.
Context
35Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni wọn yóò gbààwẹ̀.” 36Ó sì pa òwe yìí fún wọn wí pé, “Kò sí ẹni tó lè ya aṣọ tuntun kí ó sì rán mọ́, èyí tó ti gbó. Tí ó ba ṣe èyí, yóò ba aṣọ tuntun jẹ́, èyí tí ó tuntun náà kì yóò sì dọ́gba pẹ̀lú èyí tí ó ti gbó. 37Àti wí pé, kò sí ẹni tí ó lè dá ọtí wáìnì tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ, tí ó bá ṣe èyí, wáìnì tuntun yóò fa awọ náà ya, wáìnì náà yóò dànù, awọ náà a sì bàjẹ́. 38Nítorí náà, ó tọ́ kí á da wáìnì tuntun sínú awọ tuntun. 39Kò sì ẹni tí yóò fẹ́ láti mu wáìnì tuntun lẹ́yìn tí ó bá ti mu ògbólógbòó tán, nítorí yóò wí pé, ‘Èyí tí ó jẹ́ ògbólógbòó dára jù.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.