Native Bible

Luke 5:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ó ṣe é ṣe kí àwọn àlejò ọkọ ìyàwó máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ̀lú wọn bí?

Luke 5:34 in English

Luke 5:34 · Berean Standard Bible

Jesus replied, “Can you make the guests of the bridegroom fast while He is with them?

Context

32Èmí kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.” 33Wọ́n wí fún pé, “Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu a máa gbààwẹ̀, wọn a sì máa gbàdúrà, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ a máa jẹ, wọn a sì máa mu pẹ̀lú.” 34Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ó ṣe é ṣe kí àwọn àlejò ọkọ ìyàwó máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ̀lú wọn bí? 35Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni wọn yóò gbààwẹ̀.” 36Ó sì pa òwe yìí fún wọn wí pé, “Kò sí ẹni tó lè ya aṣọ tuntun kí ó sì rán mọ́, èyí tó ti gbó. Tí ó ba ṣe èyí, yóò ba aṣọ tuntun jẹ́, èyí tí ó tuntun náà kì yóò sì dọ́gba pẹ̀lú èyí tí ó ti gbó.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.